Deuteronomi 18:4
Deuteronomy 18:4 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Àkọ́so irúgbìn ọkà rẹ, ti wáìnì àti ti òróró rẹ, àti àkọ́rẹ́ irun àgùntàn rẹ ni ìwọ yóò fi fún wọn.
Deuteronomy 18:4 in English
Deuteronomy 18:4 · Berean Standard Bible
You are to give them the firstfruits of your grain, new wine, and oil, and the first wool sheared from your flock.
Context
2Wọn kì yóò ní ìní láàrín àwọn arákùnrin wọn; Olúwa ni yóò jẹ́ ìní i tiwọn, gẹ́gẹ́ bí ó ti ṣe ìlérí fún wọn. 3Gbogbo èyí ni yóò jẹ́ ìpín àwọn àlùfáà láti ọ̀dọ̀ àwọn ènìyàn tí ó fi akọ màlúù tàbí àgùntàn rú ẹbọ; wọn yóò fi èjìká àti ẹ̀rẹ̀kẹ́ méjèèjì àti gbogbo inú fún àlùfáà. 4Àkọ́so irúgbìn ọkà rẹ, ti wáìnì àti ti òróró rẹ, àti àkọ́rẹ́ irun àgùntàn rẹ ni ìwọ yóò fi fún wọn. 5Nítorí Olúwa Ọlọ́run rẹ ti yàn wọ́n àti àwọn ọmọ wọn láti inú gbogbo ẹ̀yà láti dúró àti láti ṣe ìránṣẹ́ ní orúkọ Olúwa títí láé. 6Tí ọmọ Lefi kan bá sì wá láti ibikíbi nínú àwọn ìlú u yín ní Israẹli, níbi tí ó ń gbé ṣe àtìpó, tí ó sì wá gẹ́gẹ́ bí ìfẹ́ rẹ̀ sí ibi tí Olúwa yóò yàn.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.