Deuteronomi 17:9
Deuteronomy 17:9 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ẹ lọ sí ọ̀dọ̀ àwọn àlùfáà tí í ṣe Lefi, àní sí ọ̀dọ̀ adájọ́ tí ó wà fún ìgbẹ́jọ́ ní ìgbà náà. Ẹ béèrè lọ́wọ́ wọn, wọn yóò sì ṣe ìdájọ́.
Deuteronomy 17:9 in English
Deuteronomy 17:9 · Berean Standard Bible
You are to go to the Levitical priests and to the judge who presides at that time. Inquire of them, and they will give you a verdict in the case.
Context
7Àwọn ẹlẹ́rìí ni kí ó kọ́kọ́ gbọ́wọ́ lé e láti pa á. Lẹ́yìn èyí ni kí gbogbo ènìyàn dáwọ́jọ láti pa á. Nípa báyìí, ẹ̀yin yóò sì fọ ohun búburú náà mọ́ kúrò ní àárín yín. 8Bí ẹjọ́ bá wá sí ilé ẹjọ́ èyí tí ó nira jù láti dá, yálà ìtàjẹ̀ sílẹ̀ ni, ọ̀ràn dídá tàbí ìkanni-lábùkù, ẹ mú wọn lọ sí ibi tí Olúwa Ọlọ́run yín yóò yàn. 9Ẹ lọ sí ọ̀dọ̀ àwọn àlùfáà tí í ṣe Lefi, àní sí ọ̀dọ̀ adájọ́ tí ó wà fún ìgbẹ́jọ́ ní ìgbà náà. Ẹ béèrè lọ́wọ́ wọn, wọn yóò sì ṣe ìdájọ́. 10Kí ìwọ kí ó sì ṣe bí ọ̀rọ̀ ìdájọ́, ti àwọn ará ibi tí Olúwa yóò yàn náà yóò fihàn ọ, kí ìwọ kí ó sì máa kíyèsí àti máa ṣe gẹ́gẹ́ bi gbogbo èyí tí wọn kọ́ ọ. 11Ẹ ṣe bí òfin tí wọ́n kọ́ ọ yín, àti ìpinnu tí wọ́n fún un yín. Ẹ má ṣe yípadà sọ́tùn tàbí sósì, kúrò nínú ohun tí wọ́n sọ fún un yín.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.