Deuteronomi 17:2
Deuteronomy 17:2 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Bí ọkùnrin tàbí obìnrin kan tó ń gbé láàrín yín ní èyíkéyìí ìlú wọ̀n-ọn-nì, tí Olúwa fún un yín bá ń ṣe ibi ní ojú Olúwa Ọlọ́run yín, ní ríré májẹ̀mú rẹ̀ kọjá,
Deuteronomy 17:2 in English
Deuteronomy 17:2 · Berean Standard Bible
If a man or woman among you in one of the towns that the LORD your God gives you is found doing evil in the sight of the LORD your God by transgressing His covenant
Context
1Ẹ má ṣe fi màlúù tàbí àgùntàn tí ó ní àbùkù, tàbí àbàwọ́n rú ẹbọ sí Olúwa Ọlọ́run yín, nítorí ìríra ni èyí yóò jẹ́ fún un. 2Bí ọkùnrin tàbí obìnrin kan tó ń gbé láàrín yín ní èyíkéyìí ìlú wọ̀n-ọn-nì, tí Olúwa fún un yín bá ń ṣe ibi ní ojú Olúwa Ọlọ́run yín, ní ríré májẹ̀mú rẹ̀ kọjá, 3èyí tí ó lòdì sí òfin mi, ó ń sin ọlọ́run mìíràn, ó ń foríbalẹ̀ fún wọn: àní sí oòrùn, òṣùpá àti àwọn ìràwọ̀ ojú ọ̀run, 4tí èyí sì dé etí ìgbọ́ ọ yín, kí ẹ wádìí ọ̀rọ̀ náà dájúdájú. Bí ó bá jẹ́ òtítọ́ tí ó sì hàn gbangba pé ó ti ṣe ohun ìríra yìí, ní Israẹli.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.