Deuteronomi 15:5
Deuteronomy 15:5 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Kìkì bí ẹ bá gbọ́rọ̀ sí àṣẹ Olúwa Ọlọ́run yín tí ẹ sì kíyèsára láti máa rìn nínú gbogbo àṣẹ wọ̀nyí, tí èmi ń pa fún un yín lónìí.
Deuteronomy 15:5 in English
Deuteronomy 15:5 · Berean Standard Bible
if only you obey the LORD your God and are careful to follow all these commandments I am giving you today.
Context
3Ẹ lè béèrè ìsanpadà lọ́dọ̀ àjèjì. Ṣùgbọ́n ẹ fa igi lé gbèsè yówù kó jẹ́ tí arákùnrin yín jẹ yín. 4Ṣùgbọ́n kò sí ẹni tí yóò tọ́ sí nínú yín, nítorí pé Olúwa Ọlọ́run yín yóò bùkún un yín lọ́pọ̀lọ́pọ̀ nínú ilẹ̀ náà tí ó ń mú un yín lọ láti gbà bí ìní yín. 5Kìkì bí ẹ bá gbọ́rọ̀ sí àṣẹ Olúwa Ọlọ́run yín tí ẹ sì kíyèsára láti máa rìn nínú gbogbo àṣẹ wọ̀nyí, tí èmi ń pa fún un yín lónìí. 6Nítorí pé Olúwa Ọlọ́run yín yóò bùkún un yín bí ó ti ṣèlérí, ẹ̀yin yóò sì máa yá ọ̀pọ̀lọpọ̀ orílẹ̀-èdè ẹ kì yóò sì tọrọ. Ẹ ó ṣàkóso ọ̀pọ̀lọpọ̀ orílẹ̀-èdè, ṣùgbọ́n kò sí orílẹ̀-èdè tí yóò lè jẹ ọba lé e yín lórí. 7Bí tálákà kan bá wà láàrín àwọn arákùnrin yín ní èyíkéyìí àwọn ìlú, ilẹ̀ náà tí Olúwa yín yóò fún un yín. Ẹ má ṣe ṣe àìláàánú, bẹ́ẹ̀ ni kí ẹ má ṣe háwọ́ sí arákùnrin yín tí ó jẹ́ tálákà.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.