Deuteronomi 15:18
Deuteronomy 15:18 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Má ṣe kà á sí ohun ìnira láti dá ẹrú rẹ sílẹ̀, nítorí ìsìnrú rẹ̀ fún ọ, ní ọdún mẹ́fà náà tó ìlọ́po méjì iṣẹ́ alágbàṣe, Olúwa Ọlọ́run rẹ yóò bùkún fún ọ nínú gbogbo ìdáwọ́lé rẹ.
Deuteronomy 15:18 in English
Deuteronomy 15:18 · Berean Standard Bible
Do not regard it as a hardship to set your servant free, because his six years of service were worth twice the wages of a hired hand. And the LORD your God will bless you in all you do.
Context
16Ṣùgbọ́n bí ìránṣẹ́ rẹ bá sọ fún ọ pé, “Èmi kò fẹ́ fi ọ́ sílẹ̀,” nítorí pé ó fẹ́ràn ìwọ àti ìdílé rẹ, tí ó sì tẹ́ ọ lọ́rùn, 17kí ìwọ kí ó mú ìlu kan lu etí rẹ̀ mọ́ ara ìlẹ̀kùn, yóò sì di ẹrú rẹ láéláé. Bẹ́ẹ̀ náà ni kí o ṣe sí ìránṣẹ́ ẹrúbìnrin rẹ. 18Má ṣe kà á sí ohun ìnira láti dá ẹrú rẹ sílẹ̀, nítorí ìsìnrú rẹ̀ fún ọ, ní ọdún mẹ́fà náà tó ìlọ́po méjì iṣẹ́ alágbàṣe, Olúwa Ọlọ́run rẹ yóò bùkún fún ọ nínú gbogbo ìdáwọ́lé rẹ. 19Gbogbo àkọ́bí tí o jẹ́ akọ nínú agbo màlúù rẹ ni kí o yà sọ́tọ̀ fún Olúwa, àti nínú agbo ewúrẹ́ bákan náà. Ẹ má ṣe fi àkọ́bí màlúù yín ṣiṣẹ́ rárá. Má ṣe rẹ́ irun àkọ́bí àgùntàn rẹ pẹ̀lú. 20Ní ọdọọdún ni kí ìwọ àti ìdílé rẹ máa jẹ ẹ́ níwájú Olúwa Ọlọ́run yín níbi tí Òun yóò yàn.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.