Native Bible

Deuteronomy 13:6 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Bí arákùnrin tìrẹ gan an ọmọ ìyá rẹ tàbí ọmọ rẹ ọkùnrin tàbí obìnrin, aya tí o fẹ́ràn jù, tàbí ọ̀rẹ́ tímọ́tímọ́ bá tàn ọ́ jẹ níkọ̀kọ̀ wí pé, “Jẹ́ kí a lọ sin ọlọ́run mìíràn” (ọlọ́run tí ìwọ tàbí baba rẹ kò mọ̀,

Deuteronomy 13:6 in English

Deuteronomy 13:6 · Berean Standard Bible

If your very own brother, or your son or daughter, or the wife you embrace,* or your closest friend secretly entices you, saying, “Let us go and worship other gods” (which neither you nor your fathers have known,

Context

4Olúwa Ọlọ́run yín ni kí ẹ tẹ̀lé, Òun ni kí ẹ bu ọlá fún, ẹ pa òfin rẹ̀ mọ́ kí ẹ sì gbọ́ tirẹ̀, ẹ sìn ín, kí ẹ sì dìímú ṣinṣin. 5Wòlíì náà tàbí alálàá náà ni kí ẹ pa, nítorí pé wàásù ìṣọ̀tẹ̀ sí Olúwa Ọlọ́run yín, tí ó mú yín jáde láti Ejibiti wá, tí ó sì rà yín padà lóko ẹrú. Ó ti gbìyànjú láti fà yín kúrò lójú ọ̀nà tí Olúwa Ọlọ́run yín ti pàṣẹ fún un yín láti máa rìn. Ẹ gbọdọ̀ yọ ibi náà kúrò láàrín yín. 6Bí arákùnrin tìrẹ gan an ọmọ ìyá rẹ tàbí ọmọ rẹ ọkùnrin tàbí obìnrin, aya tí o fẹ́ràn jù, tàbí ọ̀rẹ́ tímọ́tímọ́ bá tàn ọ́ jẹ níkọ̀kọ̀ wí pé, “Jẹ́ kí a lọ sin ọlọ́run mìíràn” (ọlọ́run tí ìwọ tàbí baba rẹ kò mọ̀, 7ọlọ́run àwọn tí ó wà láyìíká yín, yálà wọ́n jìnnà tàbí wọ́n wà nítòsí, láti òpin ilẹ̀ kan dé òmíràn), 8má ṣe fetí sí i, má sì dá sí i, má ṣe dáàbò bò ó.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.