Native Bible

Deuteronomy 13:12 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Bí ẹ̀yin bá gbọ́ tí a sọ nípa èyíkéyìí nínú àwọn ìlú u yín tí Olúwa Ọlọ́run yín fún un yín láti máa gbé,

Deuteronomy 13:12 in English

Deuteronomy 13:12 · Berean Standard Bible

If, regarding one of the cities the LORD your God is giving you to inhabit, you hear it said

Context

10Sọ ọ́ ní òkúta pa nítorí pé ó gbìyànjú láti fà ọ́ kúrò lẹ́yìn Olúwa Ọlọ́run rẹ, tí ó mú ọ jáde ti Ejibiti wá kúrò ní oko ẹrú. 11Gbogbo Israẹli yóò sì gbọ́, ẹ̀rù yóò sì bà wọ́n, kò sì sí ẹnikẹ́ni nínú yín tí yóò dán irú ibi bẹ́ẹ̀ wò mọ́. 12Bí ẹ̀yin bá gbọ́ tí a sọ nípa èyíkéyìí nínú àwọn ìlú u yín tí Olúwa Ọlọ́run yín fún un yín láti máa gbé, 13pé àwọn ènìyàn búburú, ti farahàn láàrín yín, tí ó sì ti mú kí àwọn ènìyàn ìlú wọn ṣìnà lọ, tí wọ́n wí pé, “Ẹ jẹ́ kí a lọ sin ọlọ́run mìíràn.” (àwọn ọlọ́run tí ẹ kò mọ̀.) 14Kí ẹ wádìí, ẹ béèrè, kí ẹ sì tọpinpin ọ̀rọ̀ náà dájúṣáká, bí ó bá jẹ́ òtítọ́ ni, tí ó sì hàn dájú pé ìwà ìríra yìí ti ṣẹlẹ̀ láàrín yín.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.