Deuteronomi 12:7
Deuteronomy 12:7 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Níwájú Olúwa Ọlọ́run yín níbẹ̀, kí ẹ̀yin àti ìdílé yín jẹun kí ẹ sì yó, nínú gbogbo ìdáwọ́lé e yín, torí pé Olúwa Ọlọ́run yín ti bùkún un yín.
Deuteronomy 12:7 in English
Deuteronomy 12:7 · Berean Standard Bible
There, in the presence of the LORD your God, you and your households shall eat and rejoice in all you do, because the LORD your God has blessed you.
Context
5Ṣùgbọ́n ẹ wá ibi tí Olúwa Ọlọ́run yín yóò yàn láàrín àwọn ẹ̀yà yín, láti fi orúkọ rẹ̀ síbẹ̀ bí i ibùgbé rẹ̀. Ibẹ̀ ni kí ẹ lọ. 6Níbẹ̀ ni kí ẹ mú ẹbọ sísun àti ẹbọ yín wá, ìdámẹ́wàá yín àti ọrẹ àkànṣe, àwọn ẹ̀jẹ́ yín, ọrẹ àtinúwá yín, àti àwọn àkọ́bí gbogbo màlúù yín àti ewúrẹ́ ẹ yín. 7Níwájú Olúwa Ọlọ́run yín níbẹ̀, kí ẹ̀yin àti ìdílé yín jẹun kí ẹ sì yó, nínú gbogbo ìdáwọ́lé e yín, torí pé Olúwa Ọlọ́run yín ti bùkún un yín. 8Kí ẹ̀yin kí ó má ṣe ṣe gẹ́gẹ́ bí a tí ṣe níhìn-ín lónìí yìí, tí olúkúlùkù ń ṣe ohun tí ó tọ́ ní ojú ara rẹ̀. 9Níwọ́n ìgbà tí ẹ ti dé ibi ìsinmi, àti ibi ogún tí Olúwa Ọlọ́run yín fún un yín.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.