Native Bible

Deuteronomy 12:20 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Bí Olúwa Ọlọ́run yín bá ti fẹ́ agbègbè e yín bí ó ti ṣe ìlérí, fún un yín, tí ẹ sì wí pé, àwa yóò jẹ ẹran, nítorí tí ọkàn wa fẹ́ jẹran. Ẹ jẹ ẹran náà bí ẹ tí fẹ́.

Deuteronomy 12:20 in English

Deuteronomy 12:20 · Berean Standard Bible

When the LORD your God expands your territory as He has promised, and you crave meat and say, “I want to eat meat,” you may eat it whenever you want.

Context

18Bí kò ṣe kí ẹ jẹ ẹ́ níwájú Olúwa Ọlọ́run yín, níbi tí Olúwa Ọlọ́run yín, yóò yàn: ìwọ, àwọn ọmọkùnrin rẹ, àwọn ọmọbìnrin rẹ, àwọn ìránṣẹ́kùnrin àti ìránṣẹ́bìnrin rẹ àti àwọn ọmọ Lefi láti ìlú u yín, kí ẹ sì máa yọ̀ níwájú Olúwa Ọlọ́run yín, nínú gbogbo ìdáwọ́lé e yín. 19Ẹ ṣọ́ra kí ẹ má ṣe gbàgbé àwọn Lefi, ní gbogbo ìgbà tí ẹ bá ń gbé ní ilẹ̀ ẹ yín. 20Bí Olúwa Ọlọ́run yín bá ti fẹ́ agbègbè e yín bí ó ti ṣe ìlérí, fún un yín, tí ẹ sì wí pé, àwa yóò jẹ ẹran, nítorí tí ọkàn wa fẹ́ jẹran. Ẹ jẹ ẹran náà bí ẹ tí fẹ́. 21Bí ibi tí Olúwa Ọlọ́run yín bá yàn fún orúkọ rẹ̀ bá jìnnà sí i yín, kí ẹ pa màlúù tàbí ewúrẹ́ tí Olúwa Ọlọ́run yín tí fún un yín, bí mo ti pàṣẹ fún un yín ní ìlú u yín, ẹ lè jẹ ẹ́ bí ẹ ti fẹ́. 22Ẹ jẹ wọ́n bí ẹ ó ti jẹ èsúró tàbí àgbọ̀nrín, ẹni tí a kà sí mímọ́ àti aláìmọ́ ni ó lè jẹ ẹ́.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.