Native Bible

Deuteronomy 12:13 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ẹ ṣọ́ra kí ẹ má ṣe rú ẹbọ sísun yín ní ibikíbi tí ẹ̀yin fẹ́.

Deuteronomy 12:13 in English

Deuteronomy 12:13 · Berean Standard Bible

Be careful not to offer your burnt offerings in just any place you see;

Context

11Níbi tí Olúwa Ọlọ́run yín yóò yàn bí ibùgbé fún orúkọ rẹ̀. Níbẹ̀ ni kí ẹ mú gbogbo ohun tí mo pàṣẹ fún un yín wá: àwọn ọrẹ ẹ yín àti àwọn ẹbọ sísun, ìdámẹ́wàá yín àti ọrẹ àkànṣe, àti gbogbo ohun ìní yín tí ẹ ti yàn, èyí tí ẹ ti jẹ́ ẹ̀jẹ́ fún Olúwa. 12Kí ẹ máa yọ̀ níwájú Olúwa Ọlọ́run yín níbẹ̀, ẹ̀yin, àwọn ọmọkùnrin yín, àwọn ọmọbìnrin yín, ìránṣẹ́bìnrin àti ìránṣẹ́kùnrin yín, àti àwọn Lefi láti ìlú u yín, tí wọn kò ní ìpín tàbí ogún tiwọn. 13Ẹ ṣọ́ra kí ẹ má ṣe rú ẹbọ sísun yín ní ibikíbi tí ẹ̀yin fẹ́. 14Ibi tí Olúwa yóò yàn láàrín àwọn ẹ̀yà a yín nìkan ni kí ẹ ti máa rú ẹbọ sísun yín, kí ẹ sì máa kíyèsi ohun gbogbo tí mo pàṣẹ fún un yín níbẹ̀. 15Síbẹ̀síbẹ̀, ẹ lọ pa àwọn ẹran yín ní èyíkéyìí nínú àwọn ìlú u yín, kí ẹ sì jẹ ẹran náà tó bí ẹ ti fẹ́, bí ẹ ti ń ṣe sí àgbọ̀nrín àti èsúró, gẹ́gẹ́ bí ìbùkún Olúwa Ọlọ́run yín tí ó fi fún un yín, àti ẹni mímọ́ àti aláìmọ́ ni ó lè jẹ nínú àwọn ẹran náà.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.