Deuteronomi 11:17
Deuteronomy 11:17 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Nígbà náà ni ìbínú Olúwa yóò sì ru sí i yín, Òun yóò ti ìlẹ̀kùn ọ̀run kí òjò má ba à rọ̀, ilẹ̀ kì yóò sì so èso kankan, ẹ ó sì ṣègbé ní ilẹ̀ rere tí Olúwa fi fún un yín.
Deuteronomy 11:17 in English
Deuteronomy 11:17 · Berean Standard Bible
or the anger of the LORD will be kindled against you. He will shut the heavens so that there will be no rain, nor will the land yield its produce, and you will soon perish from the good land that the LORD is giving you.
Context
15Èmi yóò mú kí koríko hù lórí ilẹ̀ yín fún àwọn ohun ọ̀sìn in yín, ẹ ó sì jẹ, ẹ ó sì yó. 16Ẹ ṣọ́ra, kí a má ba à tàn yín jẹ láti yípadà kí ẹ sì sin ọlọ́run mìíràn àti láti máa foríbalẹ̀ fún wọn. 17Nígbà náà ni ìbínú Olúwa yóò sì ru sí i yín, Òun yóò ti ìlẹ̀kùn ọ̀run kí òjò má ba à rọ̀, ilẹ̀ kì yóò sì so èso kankan, ẹ ó sì ṣègbé ní ilẹ̀ rere tí Olúwa fi fún un yín. 18Ẹ fi gbogbo ọ̀rọ̀ mi wọ̀nyí sí àyà a yín, àti ọkàn an yín, ẹ so wọ́n bí àmì sórí ọwọ́ yín, kí ẹ sì so wọ́n mọ́ iwájú orí yín. 19Ẹ máa fi wọ́n kọ́ àwọn ọmọ yín, ẹ máa sọ̀rọ̀ nípa wọn bí ẹ bá jókòó nínú ilé, àti ní ojú ọ̀nà bí ẹ bá ń rìn lọ, bí ẹ bá sùn àti bí ẹ bá jí.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.