Native Bible

Deuteronomy 10:1 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Nígbà náà ni Olúwa wí fún mi pé, “Gbé wàláà òkúta méjì bí i ti àkọ́kọ́ kí o sì gòkè tọ̀ mí wá. Kí o sì tún fi igi kan àpótí kan.

Deuteronomy 10:1 in English

Deuteronomy 10:1 · Berean Standard Bible

At that time the LORD said to me, “Chisel out two stone tablets like the originals, come up to Me on the mountain, and make an ark of wood.

Context

1Nígbà náà ni Olúwa wí fún mi pé, “Gbé wàláà òkúta méjì bí i ti àkọ́kọ́ kí o sì gòkè tọ̀ mí wá. Kí o sì tún fi igi kan àpótí kan. 2Èmi yóò sì kọ ọ̀rọ̀ tí ó wà lára wàláà àkọ́kọ́ tí ìwọ fọ́, sára wàláà wọ̀nyí. Ìwọ yóò sì fi wọ́n sínú àpótí náà.” 3Mo sì kan àpótí náà pẹ̀lú igi kasia, mo sì gbẹ́ wàláà òkúta méjì náà jáde bí i ti ìṣáájú. Mo sì gòkè lọ pẹ̀lú wàláà méjèèjì lọ́wọ́ mí.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.