Native Bible

Deuteronomy 1:6 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Olúwa Ọlọ́run wa bá wa sọ̀rọ̀ ní Horebu pé, “Ẹ ti dúró ní orí òkè yìí pẹ́ tó.

Deuteronomy 1:6 in English

Deuteronomy 1:6 · Berean Standard Bible

The LORD our God said to us at Horeb: “You have stayed at this mountain long enough.

Context

4Èyí ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn ìgbà tí ó ti ṣẹ́gun Sihoni ọba àwọn Amori, tí ó jẹ ọba ní Heṣboni, àti Ogu ọba Baṣani ni ó ṣẹ́gun ní Edrei, ẹni tí ó jẹ ọba ní Aṣtarotu. 5Ní ìhà ìlà-oòrùn Jordani tí ó wà nínú ilẹ̀ Moabu ni Mose bẹ̀rẹ̀ sísọ àsọyé òfin wọ̀nyí wí pé: 6Olúwa Ọlọ́run wa bá wa sọ̀rọ̀ ní Horebu pé, “Ẹ ti dúró ní orí òkè yìí pẹ́ tó. 7Ẹ yípadà kí ẹ sì tẹ̀síwájú ní ìrìnàjò yín lọ sí ilẹ̀ òkè àwọn ará Amori, ẹ tọ gbogbo àwọn ènìyàn tí ó ń gbé Arabah lọ ní aginjù, ní àwọn orí òkè àti pẹ̀tẹ́lẹ̀, ní gúúsù àti ní etí Òkun, lọ sí ilẹ̀ àwọn ará Kenaani àti lọ sí Lebanoni, títí fi dé odò ńlá Eufurate. 8Wò ó, èmi tí fi ilẹ̀ yí fún un yín, ẹ wọ inú rẹ̀ lọ kí ẹ sì gba ilẹ̀ náà tí Olúwa ti búra wí pé òun yóò fún àwọn baba yín: fún Abrahamu, Isaaki, àti Jakọbu, àti fún àwọn àrọ́mọdọ́mọ wọn.”

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.