Native Bible

Deuteronomy 1:2 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

(Ọjọ́ mọ́kànlá ni ó gbà láti rin ìrìnàjò láti Horebu dé Kadeṣi-Barnea, bí a bá gba ọ̀nà òkè Seiri.)

Deuteronomy 1:2 in English

Deuteronomy 1:2 · Berean Standard Bible

It is an eleven-day journey from Horeb * to Kadesh-barnea by way of Mount Seir.

Context

1Wọ̀nyí ni àwọn ọ̀rọ̀ tí Mose sọ fún gbogbo Israẹli ní aginjù, aginjù ìlà-oòrùn Jordani, ni Arabah, ní òdìkejì Ṣufi, ní àárín Parani àti Tofeli, Labani, Haserotu àti Disahabu. 2(Ọjọ́ mọ́kànlá ni ó gbà láti rin ìrìnàjò láti Horebu dé Kadeṣi-Barnea, bí a bá gba ọ̀nà òkè Seiri.) 3Ní ìgbà tí ó pé ogójì ọdún, ní ọjọ́ kìn-ín-ní oṣù kọ́kànlá, Mose sọ ohun gbogbo tí Olúwa pàṣẹ nípa àwọn ọmọ Israẹli fún wọn. 4Èyí ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn ìgbà tí ó ti ṣẹ́gun Sihoni ọba àwọn Amori, tí ó jẹ ọba ní Heṣboni, àti Ogu ọba Baṣani ni ó ṣẹ́gun ní Edrei, ẹni tí ó jẹ ọba ní Aṣtarotu.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.