Daniẹli 8:23
Daniel 8:23 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
“Ní ìgbà ìkẹyìn ìjọba wọn, nígbà tí àwọn oníwà búburú bá dé ní kíkún, ni ọba kan yóò dìde, tí ojú rẹ̀ le koko, tí ó sì mòye ọ̀rọ̀ àrékérekè.
Daniel 8:23 in English
Daniel 8:23 · Berean Standard Bible
In the latter part of their reign, when the rebellion has reached its full measure, an insolent king, skilled in intrigue, will come to the throne.
Context
21Òbúkọ onírun náà ni ọba Giriki, ìwo ńlá ti ó wà láàrín ojú u rẹ̀ ni ọba àkọ́kọ́. 22Ìwo mẹ́rin mìíràn sì dìde dúró dípò ọ̀kan tí ó ṣẹ́, èyí dúró gẹ́gẹ́ bí ìjọba mẹ́rin tí yóò dìde nínú orílẹ̀-èdè náà, ṣùgbọ́n wọn kì yóò ní ní irú agbára kan náà. 23“Ní ìgbà ìkẹyìn ìjọba wọn, nígbà tí àwọn oníwà búburú bá dé ní kíkún, ni ọba kan yóò dìde, tí ojú rẹ̀ le koko, tí ó sì mòye ọ̀rọ̀ àrékérekè. 24Yóò di alágbára, ṣùgbọ́n tí kì í ṣe nípa agbára rẹ̀. Yóò sì máa ṣe ìparun tí yóò ya ni lẹ́nu, yóò sì máa ṣe àṣeyọrí nínú ohun gbogbo tó ń ṣe. Yóò sì run àwọn alágbára àti àwọn ènìyàn mímọ́. 25Nípa àrékérekè rẹ̀, yóò mú kí ẹ̀tàn gbèrú, yóò gbé ara rẹ̀ ga nínú ọkàn rẹ̀, nígbà tí wọ́n rò wí pé àlàáfíà dé, yóò sì pa àwọn ènìyàn run, nígbà tí wọn kò rò tẹ́lẹ̀, yóò sì lòdì sí olórí àwọn ọmọ-aládé, síbẹ̀, a ó pa á run ṣùgbọ́n kì í ṣe nípa agbára ènìyàn.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.