Daniẹli 8:1
Daniel 8:1 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Nígbà tí ó di ọdún kẹta ìjọba Belṣassari ọba, èmi Daniẹli rí ìran kan èyí tí mo ti rí tẹ́lẹ̀.
Daniel 8:1 in English
Daniel 8:1 · Berean Standard Bible
In the third year of the reign of King Belshazzar, a vision appeared to me, Daniel, subsequent to the one that had appeared to me earlier.
Context
1Nígbà tí ó di ọdún kẹta ìjọba Belṣassari ọba, èmi Daniẹli rí ìran kan èyí tí mo ti rí tẹ́lẹ̀. 2Nínú ìran náà, mo rí ara mi nínú ilé ìṣọ́ ní Susa ní agbègbè ìjọba Elamu: nínú ìran náà mo wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ odò Ulai. 3Mo wo òkè mo sì rí àgbò kan tí ó ní ìwo méjì níwájú mi, ó dúró sí ẹ̀gbẹ́ odò Ulai, àwọn ìwo náà sì gùn. Ṣùgbọ́n ọ̀kan gùn ju èkejì lọ, èyí tí ó gùn jù ni ó yọ jáde kẹ́yìn.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.