Daniẹli 7:20
Daniel 7:20 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Bẹ́ẹ̀ ni mo sì fẹ́ mọ̀ nípa ìwo mẹ́wàá orí rẹ̀ àti nípa ìwo yòókù tí ó jáde, nínú èyí tí mẹ́ta lára wọn ṣubú, ìwo tí ó ní ojú, tí ẹnu rẹ̀ ń sọ̀rọ̀ ìgbéraga.
Daniel 7:20 in English
Daniel 7:20 · Berean Standard Bible
I also wanted to know about the ten horns on its head and the other horn that came up, before which three of them fell—the horn whose appearance was more imposing than the others, with eyes and with a mouth that spoke words of arrogance.
Context
18Ṣùgbọ́n, ẹni mímọ́ ti Ọ̀gá-ògo ni yóò gba ìjọba náà, yóò sì jogún un rẹ títí láé àti títí láéláé.’ 19“Nígbà náà, ni mo fẹ́ mọ ìtumọ̀ òtítọ́ ẹranko kẹrin, tí ó yàtọ̀ sí àwọn yòókù, èyí tí ó dẹ́rùba ni gidigidi, tí ó ní eyín irin àti èékánná idẹ, ẹranko tí ó ń run tí ó sì ń pajẹ, tí ó sì ń fi ẹsẹ̀ tẹ èyí tókù mọ́lẹ̀. 20Bẹ́ẹ̀ ni mo sì fẹ́ mọ̀ nípa ìwo mẹ́wàá orí rẹ̀ àti nípa ìwo yòókù tí ó jáde, nínú èyí tí mẹ́ta lára wọn ṣubú, ìwo tí ó ní ojú, tí ẹnu rẹ̀ ń sọ̀rọ̀ ìgbéraga. 21Bí mo ṣe ń wò, ìwo yìí ń bá àwọn ènìyàn mímọ́ jagun, ó sì borí i wọn, 22títí ẹni ìgbàanì fi dé, ó sì ṣe ìdájọ́ ìdáláre fún àwọn ẹni mímọ́ Ọ̀gá-ògo, àsìkò náà sì dé nígbà tí àwọn ẹni mímọ́ náà jogún ìjọba.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.