Native Bible

Daniel 6:20 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Nígbà tí ó súnmọ́ ibi ihò náà ní ibi tí Daniẹli wà, ó pe Daniẹli pẹ̀lú ìtara pé, “Daniẹli, ìránṣẹ́ Ọlọ́run alààyè, ṣé Ọlọ́run rẹ tí ìwọ ń sìn tọ̀sán tòru, lè gbà ọ́ lọ́wọ́ kìnnìún bí?”

Daniel 6:20 in English

Daniel 6:20 · Berean Standard Bible

When he reached the den, he cried out in a voice of anguish, “O Daniel, servant of the living God, has your God, whom you serve continually, been able to deliver you from the lions?”

Context

18Nígbà náà ni ọba padà sí ààfin rẹ̀, ó sì lo gbogbo òru náà láì jẹun, kò sì gbọ́ orin kankan, bẹ́ẹ̀ ni kò sì le è sùn ní òru ọjọ́ náà. 19Ní òwúrọ̀ kùtùkùtù, ni ọba dìde ó sì sáré lọ sí ibi ihò kìnnìún náà. 20Nígbà tí ó súnmọ́ ibi ihò náà ní ibi tí Daniẹli wà, ó pe Daniẹli pẹ̀lú ìtara pé, “Daniẹli, ìránṣẹ́ Ọlọ́run alààyè, ṣé Ọlọ́run rẹ tí ìwọ ń sìn tọ̀sán tòru, lè gbà ọ́ lọ́wọ́ kìnnìún bí?” 21Daniẹli sì dáhùn wí pé, “Ọba kí ẹ pẹ́! 22Ọlọ́run mi rán angẹli i rẹ̀, ó sì dí àwọn kìnnìún lẹ́nu. Wọn kò le è pa mí lára, nítorí a rí mi gẹ́gẹ́ bí aláìlẹ́ṣẹ̀ ní iwájú rẹ̀. Bẹ́ẹ̀ ni èmi kò hu ìwà ìbàjẹ́ kan níwájú rẹ ìwọ ọba.”

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.