Native Bible

Daniel 6:17 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

A sì gbé òkúta kan wá, wọ́n sì fi dí ẹnu ihò náà, ọba sì dì í pa pẹ̀lú òrùka èdìdì rẹ̀ àti pẹ̀lú òrùka àwọn ọlọ́lá rẹ̀, nítorí kí a má ṣe yí ohunkóhun padà nítorí i Daniẹli.

Daniel 6:17 in English

Daniel 6:17 · Berean Standard Bible

A stone was brought and placed over the mouth of the den, and the king sealed it with his own signet ring and with the rings of his nobles, so that nothing concerning Daniel could be changed.

Context

15Nígbà náà, ni àwọn ọlọ̀tẹ̀ wọ̀nyí kó ara wọn jọ wá sí ọ̀dọ̀ ọba, wọ́n sì wí fún un pé, “Ìwọ ọba rántí pé, ní ìbámu pẹ̀lú òfin àwọn Media àti Persia kò sí àṣẹ tàbí ìkéde tí ọba ṣe tí a le è yí i padà.” 16Nígbà náà, ni ọba pàṣẹ, wọ́n sì mú Daniẹli, wọ́n sì sọ ọ́ sínú ihò kìnnìún. Ọba sì sọ fún Daniẹli pé, “Kí Ọlọ́run rẹ tí ìwọ ń sìn nígbà gbogbo kí ó gbà ọ́!” 17A sì gbé òkúta kan wá, wọ́n sì fi dí ẹnu ihò náà, ọba sì dì í pa pẹ̀lú òrùka èdìdì rẹ̀ àti pẹ̀lú òrùka àwọn ọlọ́lá rẹ̀, nítorí kí a má ṣe yí ohunkóhun padà nítorí i Daniẹli. 18Nígbà náà ni ọba padà sí ààfin rẹ̀, ó sì lo gbogbo òru náà láì jẹun, kò sì gbọ́ orin kankan, bẹ́ẹ̀ ni kò sì le è sùn ní òru ọjọ́ náà. 19Ní òwúrọ̀ kùtùkùtù, ni ọba dìde ó sì sáré lọ sí ibi ihò kìnnìún náà.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.