Daniẹli 6:11
Daniel 6:11 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Nígbà náà ni, àwọn ọlọ̀tẹ̀ yìí kó ara wọn jọ, wọ́n sì rí Daniẹli tí ó ń gba àdúrà, ó sì ń bẹ̀bẹ̀ fún àánú lọ́dọ̀ Ọlọ́run.
Daniel 6:11 in English
Daniel 6:11 · Berean Standard Bible
Then these men went as a group and found Daniel petitioning and imploring his God.
Context
9Nígbà náà, ni Dariusi ọba fi ọwọ́ sí ìwé àṣẹ náà. 10Lóòótọ́, Daniẹli mọ̀ pé a ti fi ọwọ́ sí ìwé òfin náà, síbẹ̀ ó wọ ilé e rẹ̀ lọ, nínú yàrá òkè, ó ṣí fèrèsé èyí tí ó kọjú sí Jerusalẹmu sílẹ̀. Ó kúnlẹ̀ lórí orúnkún un rẹ̀ ní ẹ̀ẹ̀mẹ́ta lójoojúmọ́, ó gbàdúrà, ó fi ọpẹ́ fún Ọlọ́run gẹ́gẹ́ bí ìṣe rẹ̀ tẹ́lẹ̀. 11Nígbà náà ni, àwọn ọlọ̀tẹ̀ yìí kó ara wọn jọ, wọ́n sì rí Daniẹli tí ó ń gba àdúrà, ó sì ń bẹ̀bẹ̀ fún àánú lọ́dọ̀ Ọlọ́run. 12Wọ́n lọ sí iwájú ọba, wọ́n sì rán ọba létí nípa òfin tí ó ṣe pé, “Ìwọ kò ha fi ọwọ́ sí òfin wí pé ní ìwọ̀n ọgbọ̀n ọjọ́ ẹnikẹ́ni tí ó bá gba àdúrà sí Ọlọ́run tàbí ènìyàn, láì bá ṣe ìwọ ọba, a ó gbé e jù sínú ihò kìnnìún?”
Ọba sì dáhùn pé, “Àṣẹ náà dúró síbẹ̀, ní ìbámu pẹ̀lú òfin àwọn ará Media àti Persia, èyí tí a kò le è parẹ́.” 13Nígbà náà, ni wọ́n sọ fún ọba pé, “Daniẹli, ọ̀kan lára ìgbèkùn Juda, kò ka ìwọ ọba sí, tàbí àṣẹ ẹ̀ rẹ tí o fi ọwọ́ sí. Òun sì tún ń gba àdúrà ní ẹ̀ẹ̀mẹ́ta lójúmọ́.”
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.