Daniẹli 5:17
Daniel 5:17 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Nígbà náà ni Daniẹli dá ọba lóhùn wí pé, “Fi ẹ̀bùn rẹ pamọ́ fún ara rẹ, tàbí kí o fún ẹlòmíràn. Síbẹ̀ èmi yóò ka àkọsílẹ̀ náà fún ọba, èmi yóò sì sọ ìtumọ̀ rẹ̀.
Daniel 5:17 in English
Daniel 5:17 · Berean Standard Bible
In response, Daniel said to the king, “You may keep your gifts for yourself and give your rewards to someone else. Nevertheless, I will read the inscription for the king and interpret it for him.
Context
15A ti mú àwọn amòye àti àwọn awòràwọ̀ wá sí iwájú mí kí wọn ba à le è wá ka àkọsílẹ̀ yìí kí wọn sì sọ ìtumọ̀ rẹ̀ fún mi, ṣùgbọ́n wọn kò le è sọ ìtumọ̀ ohun tí ó jẹ́. 16Ṣùgbọ́n mo ti gbọ́ wí pé, ìwọ lè sọ ìtumọ̀, àti wí pé o lè yanjú àwọn ìṣòro tó lágbára. Tí o bá lè ka àkọsílẹ̀ ìwé yìí kí o sì sọ ìtumọ̀ rẹ̀, a ó fi aṣọ elése àlùkò wọ̀ ọ́ pẹ̀lú ẹ̀gbà wúrà ni a ó fi sí ọ lọ́rùn, a ó sì fi ọ́ ṣe olórí kẹta ní ìjọba mi.” 17Nígbà náà ni Daniẹli dá ọba lóhùn wí pé, “Fi ẹ̀bùn rẹ pamọ́ fún ara rẹ, tàbí kí o fún ẹlòmíràn. Síbẹ̀ èmi yóò ka àkọsílẹ̀ náà fún ọba, èmi yóò sì sọ ìtumọ̀ rẹ̀. 18“Ìwọ ọba, Ọlọ́run Ọ̀gá-ògo fún Nebukadnessari baba rẹ ní ìjọba, títóbi ògo àti ọlá. 19Nítorí ipò ńlá tí a fi fún un, gbogbo ènìyàn orílẹ̀-èdè àti èdè gbogbo fi ń páyà tí wọ́n sì ń bẹ̀rù rẹ̀. Ó ń pa àwọn tí ó bá wù ú, ó sì ń dá àwọn tí ó bá wù ú sí, ó ń gbé àwọn tí ó bá wù ú ga, ó sì ń rẹ àwọn tí ó bá wù ú sílẹ̀.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.