Native Bible

Daniel 4:35 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Gbogbo àwọn ènìyàn ayé ni a kà sí asán. Ó ń ṣe bí ó ti wù ú, pẹ̀lú àwọn ogun ọ̀run, àti gbogbo àwọn ènìyàn ayé tí kò sì ṣí ẹnìkankan tí ó lè dí i lọ́wọ́ tàbí sọ fún un wí pé: “Kí ni ìwọ ń ṣe?”

Daniel 4:35 in English

Daniel 4:35 · Berean Standard Bible

All the peoples of the earth are counted as nothing, and He does as He pleases with the army of heaven and the peoples of the earth. There is no one who can restrain His hand or say to Him, ‘What have You done?’”

Context

33Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ ni ohun tí a sọ nípa Nebukadnessari ṣẹlẹ̀ sí i. A lé e kúrò láàrín ènìyàn, ó sì ń jẹ koríko bí i màlúù, ìrì ọ̀run sì ń sẹ̀ sí ara rẹ̀, títí irun orí rẹ̀ fi gùn bí i ti ìyẹ́ ẹyẹ idì, tí èékánná rẹ̀ sì dàbí i ti ẹyẹ. 34Ní òpin ìgbà náà, èmi, Nebukadnessari gbé ojú mi sókè sí ọ̀run, iyè mi sì sọjí. Mo fi ọpẹ́ fún Ọ̀gá-ògo; mo fi ọlá àti ògo fún ẹni tí ó wà láéláé. Ìjọba rẹ̀ ìjọba títí ayé ni ìjọba rẹ̀ wà láti ìran dé ìran. 35Gbogbo àwọn ènìyàn ayé ni a kà sí asán. Ó ń ṣe bí ó ti wù ú, pẹ̀lú àwọn ogun ọ̀run, àti gbogbo àwọn ènìyàn ayé tí kò sì ṣí ẹnìkankan tí ó lè dí i lọ́wọ́ tàbí sọ fún un wí pé: “Kí ni ìwọ ń ṣe?” 36Ní àkókò kan náà, iyè mi padà, ọlá àti ògo dídán mi padà tọ̀ mí wá fún ògo ìjọba mi. Àwọn ìgbìmọ̀ àti àwọn ọlọ́lá mi, wá mi rí, wọ́n sì dá mi padà sórí ìjọba mi, mo sì di alágbára ju ti ìṣáájú lọ. 37Báyìí, èmi, Nebukadnessari fi ọpẹ́, mo sì gbé Ọlọ́run ga, mo sì fi ògo fún ọba ọ̀run, nítorí pé gbogbo nǹkan tí ó ṣe ló dára, gbogbo ọ̀nà rẹ̀ sì tọ́. Gbogbo àwọn tó sì ń rìn ní ìgbéraga ni ó le rẹ̀ sílẹ̀.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.