Native Bible

Daniel 4:31 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Bí ọba ṣe ń sọ ọ̀rọ̀ náà lọ́wọ́ ohùn kan wá láti ọ̀run, “Ìwọ Nebukadnessari ọba, ìwọ ni a ti pàṣẹ nípa rẹ̀, a ti gba ìjọba à rẹ kúrò ní ọwọ́ ọ̀ rẹ.

Daniel 4:31 in English

Daniel 4:31 · Berean Standard Bible

While the words were still in the king’s mouth, a voice came from heaven: “It is decreed to you, King Nebuchadnezzar, that the kingdom has departed from you.

Context

29Lẹ́yìn oṣù kejìlá, bí ọba ṣe ń rìn káàkiri lórí òrùlé ààfin ìjọba Babeli, 30ó sọ pé, “Èyí ha kọ́ ni Babeli ńlá tí mo kọ́ gẹ́gẹ́ bí ilé ọba, nípa agbára à mi àti fún ògo ọláńlá à mi?” 31Bí ọba ṣe ń sọ ọ̀rọ̀ náà lọ́wọ́ ohùn kan wá láti ọ̀run, “Ìwọ Nebukadnessari ọba, ìwọ ni a ti pàṣẹ nípa rẹ̀, a ti gba ìjọba à rẹ kúrò ní ọwọ́ ọ̀ rẹ. 32A ó lé ọ kúrò láàrín àwọn ènìyàn, ìwọ yóò sì lọ máa gbé àárín àwọn ẹranko igbó; ìwọ yóò jẹ koríko bí i màlúù, ìgbà méje yóò kọjá lórí i rẹ títí ìwọ yóò fi mọ̀ wí pé, Ọ̀gá-ògo jẹ ọba lórí ìjọba ènìyàn àti pé ó ń fi fún ẹni tí ó bá wù ú.” 33Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ ni ohun tí a sọ nípa Nebukadnessari ṣẹlẹ̀ sí i. A lé e kúrò láàrín ènìyàn, ó sì ń jẹ koríko bí i màlúù, ìrì ọ̀run sì ń sẹ̀ sí ara rẹ̀, títí irun orí rẹ̀ fi gùn bí i ti ìyẹ́ ẹyẹ idì, tí èékánná rẹ̀ sì dàbí i ti ẹyẹ.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.