Native Bible

Daniel 4:11 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Igi náà tóbi, ó sì lágbára, orí rẹ̀ sì ń kan ọ̀run; a sì rí i títí dé òpin ayé.

Daniel 4:11 in English

Daniel 4:11 · Berean Standard Bible

The tree grew large and strong; its top reached the sky, and it was visible to the ends of the earth.

Context

9Mo wí pé, “Belṣassari, olórí àwọn amòye, èmi mọ̀ wí pé ẹ̀mí ọlọ́run mímọ́ wà nínú rẹ, kò sì ṣí àṣírí kan tí ó ṣòro jù fún ọ. Sọ àlá mi kí o sì túmọ̀ rẹ̀ fún mi. 10Èyí ni ìran náà tí mo rí nígbà tí mo wà lórí ibùsùn mi, mo rí igi kan láàrín ayé, igi náà ga gidigidi. 11Igi náà tóbi, ó sì lágbára, orí rẹ̀ sì ń kan ọ̀run; a sì rí i títí dé òpin ayé. 12Ewé rẹ̀ lẹ́wà, èso rẹ̀ sì pọ̀, ó sì ń pèsè oúnjẹ fún gbogbo ènìyàn. Abẹ́ ẹ rẹ̀ ni àwọn ẹranko igbó fi ṣe ibùgbé, àwọn ẹyẹ ojú ọ̀run sì ń gbé ní ẹ̀ka rẹ̀, nínú rẹ̀ ni gbogbo alààyè ti ń jẹ. 13“Lórí ibùsùn mi, mo rí ìran náà, olùṣọ́ kan dúró síwájú u mi, àní ẹni mímọ́ kan, ó ń bọ̀ wá láti ọ̀run

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.