Daniẹli 2:35
Daniel 2:35 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Nígbà náà ni irin, amọ̀, idẹ, fàdákà àti wúrà fọ́ sí wẹ́wẹ́ lẹ́sẹ̀kan náà, ó sì dàbí ìyàngbò tí a fẹ́ kúrò lórí ọkà ní àsìkò ẹ̀ẹ̀rùn. Afẹ́fẹ́ gbé gbogbo rẹ̀ lọ láìṣẹ́ku ọ̀kan mọ́, òkúta tí ó fọ́ ère náà sì di òkè ńlá, ó sì gba gbogbo ayé.
Daniel 2:35 in English
Daniel 2:35 · Berean Standard Bible
Then the iron, clay, bronze, silver, and gold were shattered and became like chaff on the threshing floor in summer. The wind carried them away, and not a trace of them could be found. But the stone that had struck the statue became a great mountain and filled the whole earth.
Context
33àwọn ẹsẹ̀ rẹ̀ jẹ́ irin, àwọn àtẹ́lẹsẹ̀ rẹ̀ jẹ́ apá kan irin àti apá kan amọ̀. 34Bí ó ṣe ń wò, òkúta kan wá, tí kò wá láti ọwọ́ ẹnìkankan. Ó kọlu ère náà ní àtẹ́lẹsẹ̀ irin àti amọ̀, ó sì fọ́ wọn sí wẹ́wẹ́. 35Nígbà náà ni irin, amọ̀, idẹ, fàdákà àti wúrà fọ́ sí wẹ́wẹ́ lẹ́sẹ̀kan náà, ó sì dàbí ìyàngbò tí a fẹ́ kúrò lórí ọkà ní àsìkò ẹ̀ẹ̀rùn. Afẹ́fẹ́ gbé gbogbo rẹ̀ lọ láìṣẹ́ku ọ̀kan mọ́, òkúta tí ó fọ́ ère náà sì di òkè ńlá, ó sì gba gbogbo ayé. 36“Èyí ni àlá náà, nígbà yìí ni a ó wá sọ ìtumọ̀ rẹ̀ fún ọba. 37Ìwọ ọba jẹ́ ọba àwọn ọba. Ọlọ́run ọ̀run ti fi ìjọba agbára, títóbi àti ògo fún ọ;
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.