Native Bible

Daniel 2:32 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Orí ère náà jẹ́ kìkì wúrà, àyà rẹ̀ àti ọwọ́ rẹ̀ jẹ́ fàdákà, inú àti ẹ̀gbẹ́ itan rẹ̀ jẹ́ idẹ,

Daniel 2:32 in English

Daniel 2:32 · Berean Standard Bible

The head of the statue was pure gold, its chest and arms were silver, its belly and thighs were bronze,

Context

30Ṣùgbọ́n fún èmi, a fi àṣírí yìí hàn mí, kì í ṣe pé mo ní ọgbọ́n tí ó pọ̀ ju ti alààyè kankan lọ, ṣùgbọ́n nítorí kí ọba lè mọ ìtumọ̀ àlá àti kí ó lè mọ ohun tí ó wà ní ọkàn rẹ̀. 31“Ìwọ ọba ń wo, ère ńlá kan tí ó dúró níwájú rẹ, ère náà ga, ó sì dára láti wò, ìrísí i rẹ̀ ba ni lẹ́rù jọjọ. 32Orí ère náà jẹ́ kìkì wúrà, àyà rẹ̀ àti ọwọ́ rẹ̀ jẹ́ fàdákà, inú àti ẹ̀gbẹ́ itan rẹ̀ jẹ́ idẹ, 33àwọn ẹsẹ̀ rẹ̀ jẹ́ irin, àwọn àtẹ́lẹsẹ̀ rẹ̀ jẹ́ apá kan irin àti apá kan amọ̀. 34Bí ó ṣe ń wò, òkúta kan wá, tí kò wá láti ọwọ́ ẹnìkankan. Ó kọlu ère náà ní àtẹ́lẹsẹ̀ irin àti amọ̀, ó sì fọ́ wọn sí wẹ́wẹ́.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.