Native Bible

Daniel 2:28 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

ṣùgbọ́n, Ọlọ́run kan ń bẹ ní ọ̀run tí ó ń fi àṣírí hàn. Ó ti fihan ọba Nebukadnessari, ohun tí yóò ṣẹlẹ̀ ní ìkẹyìn ọjọ́. Àlá àti ìran tí o rí nígbà tí o dùbúlẹ̀ lórí ibùsùn rẹ ni ìwọ̀nyí:

Daniel 2:28 in English

Daniel 2:28 · Berean Standard Bible

But there is a God in heaven who reveals mysteries, and He has made known to King Nebuchadnezzar what will happen in the latter days. Your dream and the visions that came into your mind as you lay on your bed were these:

Context

26Ọba béèrè lọ́wọ́ Daniẹli ẹni tí a tún ń pè ní Belṣassari pé, “Ṣé ìwọ lè sọ ohun tí mo rí nínú àlá mi àti ìtumọ̀ ọ rẹ̀ fún mi?” 27Daniẹli dá ọba lóhùn pé, “Kò sí awòràwọ̀ kan, apògèdè, onídán tàbí aláfọ̀ṣẹ tí ó lè ṣe àlàyé àṣírí tí ọba béèrè fún 28ṣùgbọ́n, Ọlọ́run kan ń bẹ ní ọ̀run tí ó ń fi àṣírí hàn. Ó ti fihan ọba Nebukadnessari, ohun tí yóò ṣẹlẹ̀ ní ìkẹyìn ọjọ́. Àlá àti ìran tí o rí nígbà tí o dùbúlẹ̀ lórí ibùsùn rẹ ni ìwọ̀nyí: 29“Ọba, bí ìwọ ṣe sùn sórí ibùsùn rẹ, bẹ́ẹ̀ ni ọkàn rẹ ń ro àwọn ohun tó ń bọ̀, olùfihàn àṣírí ń fi ohun tí yóò ṣẹlẹ̀ fún ọ. 30Ṣùgbọ́n fún èmi, a fi àṣírí yìí hàn mí, kì í ṣe pé mo ní ọgbọ́n tí ó pọ̀ ju ti alààyè kankan lọ, ṣùgbọ́n nítorí kí ọba lè mọ ìtumọ̀ àlá àti kí ó lè mọ ohun tí ó wà ní ọkàn rẹ̀.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.