Daniẹli 11:36
Daniel 11:36 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
“Ọba yóò ṣe bí ó ti wù ú yóò sì gbé ara rẹ̀ ga, ju gbogbo òrìṣà lọ, yóò máa sọ àwọn ọ̀rọ̀ tí kò-ṣe-é-gbọ́-létí sí Ọlọ́run àwọn Ọlọ́run, yóò sì máa yege títí àkókò ìbínú yóò fi parí, nítorí ohun tí a ti pinnu yóò ṣẹlẹ̀.
Daniel 11:36 in English
Daniel 11:36 · Berean Standard Bible
Then the king will do as he pleases and will exalt and magnify himself above every god, and he will speak monstrous things against the God of gods. He will be successful until the time of wrath is completed, for what has been decreed must be accomplished.
Context
34Nígbà tí wọ́n bá ṣubú, wọn yóò rí ìrànlọ́wọ́ díẹ̀, ọ̀pọ̀ àwọn tó ṣe aláìṣòótọ́ yóò sì darapọ̀ mọ́ wọn. 35Lára àwọn tí ó mòye yóò kọsẹ̀, nítorí kí a ba à tún wọn ṣe, wọ́n di mímọ́ àti aláìlábàwọ́n títí di ìgbà ìkẹyìn nítorí yóò sì wá ní àkókò tí a yàn. 36“Ọba yóò ṣe bí ó ti wù ú yóò sì gbé ara rẹ̀ ga, ju gbogbo òrìṣà lọ, yóò máa sọ àwọn ọ̀rọ̀ tí kò-ṣe-é-gbọ́-létí sí Ọlọ́run àwọn Ọlọ́run, yóò sì máa yege títí àkókò ìbínú yóò fi parí, nítorí ohun tí a ti pinnu yóò ṣẹlẹ̀. 37Òun kò ní ka òrìṣà àwọn baba rẹ̀ sí tàbí èyí tí àwọn fẹ́, òun kò ní ka nǹkan kan sí, ṣùgbọ́n yóò gbé ara rẹ̀ ga ju gbogbo wọn lọ. 38Ṣùgbọ́n dípò wọn, yóò bu ọlá fún òrìṣà àwọn ìlú olódi: òrìṣà tí àwọn baba rẹ̀ kò mọ̀ ni yóò bu ọlá fún pẹ̀lú wúrà àti fàdákà, pẹ̀lú òkúta iyebíye àti ẹ̀bùn tí ó lówó lórí.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.