Native Bible

Daniel 11:2 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

“Ní ìsinsin yìí, mo sọ òtítọ́ fún ọ ọba mẹ́ta yóò dìde sí i ní Persia, àti ẹ̀kẹrin tí yóò jẹ́ ọlọ́rọ̀ ju gbogbo wọn lọ. Tí ó bá ti di alágbára nípa ọrọ̀ rẹ̀, yóò sì ru gbogbo wọn sókè lòdì sí ìjọba Giriki.

Daniel 11:2 in English

Daniel 11:2 · Berean Standard Bible

Now then, I will tell you the truth: Three more kings will arise in Persia, and then a fourth, who will be far richer than all the others. By the power of his wealth, he will stir up everyone against the kingdom of Greece.*

Context

1Ní ọdún kìn-ín-ní Dariusi ará Media, mo dúró láti tì í lẹ́yìn àti láti dáàbò bò ó.) 2“Ní ìsinsin yìí, mo sọ òtítọ́ fún ọ ọba mẹ́ta yóò dìde sí i ní Persia, àti ẹ̀kẹrin tí yóò jẹ́ ọlọ́rọ̀ ju gbogbo wọn lọ. Tí ó bá ti di alágbára nípa ọrọ̀ rẹ̀, yóò sì ru gbogbo wọn sókè lòdì sí ìjọba Giriki. 3Nígbà náà ni ọba alágbára kan yóò fi ara hàn, yóò ṣe àkóso pẹ̀lú agbára ńlá, yóò sì ṣe bí ó ti wù ú. 4Lẹ́yìn ìgbà tí ó bá fi ara hàn tán, ìjọba rẹ̀ yóò fọ́, yóò sì pín sí mẹ́rin ní orígun mẹ́rẹ̀ẹ̀rin ayé, ìjọba náà kò sì ṣọ́wọ́ àwọn ìran rẹ̀ tàbí kí ó ní agbára tí ó ń lò tẹ́lẹ̀, nítorí, a ó fa ìjọba rẹ̀ tu a ó sì fi fún àwọn mìíràn.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.