Daniẹli 10:9
Daniel 10:9 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Nígbà náà, ni mo gbọ́ tí ó ń sọ̀rọ̀, bí mo ṣe tẹ́tí sílẹ̀ sí i, mo sùn lọ fọnfọn, ní ìdojúbolẹ̀.
Daniel 10:9 in English
Daniel 10:9 · Berean Standard Bible
I heard the sound of his words, and as I listened, I fell into a deep sleep, with my face to the ground.
Context
7Èmi Daniẹli, ni ẹnìkan tí ó rí ìran náà, àwọn ọkùnrin tí ó wà pẹ̀lú u mi, wọn kò rí i, ṣùgbọ́n ìpayà ńlá dà bò wọ́n, wọ́n sálọ wọ́n sì fi ara pamọ́. 8Ó sì ku èmi nìkan, tí mo rí ìran ńlá yìí, kò sì ku okun kankan fún mi, ojú u mi sì rẹ̀wẹ̀sì gidigidi, n kò sì ní agbára mọ́. 9Nígbà náà, ni mo gbọ́ tí ó ń sọ̀rọ̀, bí mo ṣe tẹ́tí sílẹ̀ sí i, mo sùn lọ fọnfọn, ní ìdojúbolẹ̀. 10Ọwọ́ kan kàn mí, ó gbé mi dìde ní ìwárìrì lórí ọwọ́ àti eékún mi. 11Ó sọ pé, “Daniẹli ẹni tí a yàn fẹ́ gidigidi gba ọ̀rọ̀ tí mo fẹ́ bá ọ sọ yìí yẹ̀ wò dáradára, kí o sì dìde, nítorí tí a rán mi sí ọ.” Bí ó ṣe sọ èyí fún mi, mo dìde ní ìwárìrì.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.