Daniẹli 10:16
Daniel 10:16 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Nígbà náà, ni ẹnìkan tí ó rí bí ènìyàn fi ọwọ́ kan ètè mi, mo la ẹnu mi, mo sì bẹ̀rẹ̀ sí ní sọ ọ̀rọ̀, mo sọ fún ẹni tí ó dúró níwájú mi, “Ìrònú sì mú mi, nítorí ìran náà, olúwa mi, n kò sì ní okun.
Daniel 10:16 in English
Daniel 10:16 · Berean Standard Bible
And suddenly one with the likeness of a man * touched my lips, and I opened my mouth and said to the one standing before me, “My lord, because of the vision, I am overcome with anguish, and I have no strength.
Context
14Ní ìsinsin yìí mo wá láti ṣàlàyé ohun tí yóò ṣẹlẹ̀ sí àwọn ènìyàn rẹ ní ọjọ́ iwájú, nítorí ìran náà ń sọ nípa ọjọ́ iwájú.” 15Bí ó sì ti ń sọ nǹkan wọ̀nyí fún mi, mo sì dorí kodò mo sì dákẹ́. 16Nígbà náà, ni ẹnìkan tí ó rí bí ènìyàn fi ọwọ́ kan ètè mi, mo la ẹnu mi, mo sì bẹ̀rẹ̀ sí ní sọ ọ̀rọ̀, mo sọ fún ẹni tí ó dúró níwájú mi, “Ìrònú sì mú mi, nítorí ìran náà, olúwa mi, n kò sì ní okun. 17Ǹjẹ́ báwo ni èmi ìránṣẹ́ ẹ̀ rẹ ṣe lè bá ọ sọ̀rọ̀, olúwa mi? Agbára mi ti lọ, agbára káká ni mo fi ń mí.” 18Ẹ̀wẹ̀, ẹnìkan tí ó rí bí ènìyàn fi ọwọ́ kàn mí, ó sì fún mi ní agbára.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.