Native Bible

Daniel 1:2 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Olúwa sì fa Jehoiakimu ọba Juda lé e lọ́wọ́, pẹ̀lú àwọn ohun èlò ilé Ọlọ́run. Àwọn nǹkan wọ̀nyí ni ó kó lọ sí ilé òrìṣà ní Babeli, sí inú ilé ìṣúra òrìṣà rẹ̀.

Daniel 1:2 in English

Daniel 1:2 · Berean Standard Bible

And the Lord delivered into his hand Jehoiakim king of Judah, along with some of the articles from the house of God. He carried these off to the land of Shinar,* to the house of his god, where he put them in the treasury of his god.

Context

1Ní ọdún kẹta tí Jehoiakimu jẹ ọba Juda, Nebukadnessari ọba Babeli wá sí Jerusalẹmu, ó sì kọlù ú pẹ̀lú àwọn ọmọ-ogun rẹ̀. 2Olúwa sì fa Jehoiakimu ọba Juda lé e lọ́wọ́, pẹ̀lú àwọn ohun èlò ilé Ọlọ́run. Àwọn nǹkan wọ̀nyí ni ó kó lọ sí ilé òrìṣà ní Babeli, sí inú ilé ìṣúra òrìṣà rẹ̀. 3Nígbà náà ni ọba pàṣẹ fún Aṣipenasi, olórí àwọn ìwẹ̀fà ààfin rẹ̀ pé, kí ó mú nínú àwọn ọmọ Israẹli tí wọ́n wá láti ìdílé ọba àti lára àwọn tí ó wá láti ilé ọlá. 4Àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin tí kò ní àbùkù ara, tí wọ́n rẹwà, tí wọ́n sì fi ìfẹ́ sí ẹ̀kọ́ hàn, tí wọ́n sì ní ìmọ̀, tí òye tètè ń yé àti àwọn tí ó kún ojú òsùwọ̀n láti ṣiṣẹ́ ní ààfin ọba kí ó kọ́ wọ́n ní èdè àti onírúurú ẹ̀kọ́ ìwé ti àwọn Babeli.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.