Native Bible

Daniel 1:17 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ọlọ́run fún àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin mẹ́rẹ̀ẹ̀rin wọ̀nyí ní ìmọ̀ àti òye nínú gbogbo onírúurú ìwé àti ẹ̀kọ́ ọ wọn: Daniẹli sì ní òye ìran àti àlá ní oríṣìíríṣìí.

Daniel 1:17 in English

Daniel 1:17 · Berean Standard Bible

To these four young men God gave knowledge and understanding in every kind of literature and wisdom. And Daniel had insight into all kinds of visions and dreams.

Context

15Lẹ́yìn ọjọ́ kẹwàá ara wọn le, wọ́n sì sanra ju àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin tí wọ́n ń jẹ oúnjẹ ọba lọ. 16Bẹ́ẹ̀ ni olùṣọ́ mú oúnjẹ àdídùn àti wáìnì tí ó yẹ kí wọ́n mu kúrò, ó sì fún wọn ní ewébẹ̀ dípò rẹ̀. 17Ọlọ́run fún àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin mẹ́rẹ̀ẹ̀rin wọ̀nyí ní ìmọ̀ àti òye nínú gbogbo onírúurú ìwé àti ẹ̀kọ́ ọ wọn: Daniẹli sì ní òye ìran àti àlá ní oríṣìíríṣìí. 18Ní òpin ìgbà tí ọba dá, pé kí a mú wọn wá sínú ààfin, olórí àwọn ìwẹ̀fà mú wọn wá síwájú ọba Nebukadnessari. 19Ọba sì bá wọn sọ̀rọ̀, ó sì rí i pé kò sí ẹni tí ó dàbí i Daniẹli, Hananiah, Miṣaeli àti Asariah; nítorí náà wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí ní ṣe iṣẹ́ ọba.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.