Native Bible

Daniel 1:10 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

ṣùgbọ́n olórí àwọn ìwẹ̀fà sọ fún Daniẹli pé, “Mo bẹ̀rù olúwa mi, ẹni tí o ti pèsè oúnjẹ àti ohun mímu rẹ. Báwo ni ìrísí rẹ yóò ṣe burú jù ti àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin ẹlẹgbẹ́ ẹ̀ rẹ lọ? Nígbà náà ni èmi yóò fi orí mi wéwu lọ́dọ̀ ọba.”

Daniel 1:10 in English

Daniel 1:10 · Berean Standard Bible

but he said to Daniel, “I fear my lord the king, who has assigned your food and drink. For why should he see your faces looking thinner than those of the other young men your age? You would endanger my head before the king!”

Context

8Ṣùgbọ́n Daniẹli pinnu ní ọkàn ara rẹ̀ pé òun kò ní ba ara òun jẹ́ pẹ̀lú oúnjẹ àti wáìnì ọba, nígbà náà ni ó gba ààyè lọ́wọ́ olórí àwọn ìwẹ̀fà wí pé òun kò fẹ́ ba ara òun jẹ́ ní ọ̀nà yìí. 9Ọlọ́run mú kí Daniẹli rí ojúrere àti àánú gbà láti ọwọ́ olórí àwọn ìwẹ̀fà, 10ṣùgbọ́n olórí àwọn ìwẹ̀fà sọ fún Daniẹli pé, “Mo bẹ̀rù olúwa mi, ẹni tí o ti pèsè oúnjẹ àti ohun mímu rẹ. Báwo ni ìrísí rẹ yóò ṣe burú jù ti àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin ẹlẹgbẹ́ ẹ̀ rẹ lọ? Nígbà náà ni èmi yóò fi orí mi wéwu lọ́dọ̀ ọba.” 11Nígbà náà ni Daniẹli sọ fún olùṣọ́ tí olórí àwọn ìwẹ̀fà yàn lórí i Daniẹli, Hananiah, Miṣaeli àti Asariah pé, 12“Jọ̀wọ́ dán àwa ìránṣẹ́ rẹ wò fún ọjọ́ mẹ́wàá. Má ṣe fún wa ní ohun kankan, àfi ewébẹ̀ láti jẹ àti omi láti mu.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.