Kolose 4:9
Colossians 4:9 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Òun sì ń bọ̀ pẹ̀lú Onesimu, arákùnrin olóòtítọ́ àti olùfẹ́, ẹni tí í ṣe ọ̀kan nínú yín. Àwọn ní yóò sọ ohun gbogbo tí à ń ṣe níhìn-ín yìí fún un yín.
Colossians 4:9 in English
Colossians 4:9 · Berean Standard Bible
With him I am sending Onesimus, our faithful and beloved brother, who is one of you. They will tell you about everything here.
Context
7Gbogbo bí nǹkan ti rí fún mi ní Tikiku yóò jẹ́ kí ẹ mọ̀. Òun jẹ́ arákùnrin olùfẹ́ àti olóòtítọ́ ìránṣẹ́ àti ẹlẹgbẹ́ nínú Olúwa, 8ẹni tí èmí ń rán sí yín nítorí èyí kan náà, kí ẹ̀yin lè mọ́ bí a ti wà, kí òun kí ó lè tu ọkàn yín nínú. 9Òun sì ń bọ̀ pẹ̀lú Onesimu, arákùnrin olóòtítọ́ àti olùfẹ́, ẹni tí í ṣe ọ̀kan nínú yín. Àwọn ní yóò sọ ohun gbogbo tí à ń ṣe níhìn-ín yìí fún un yín. 10Aristarku, ẹlẹgbẹ́ mí nínú túbú kí i yín, àti Marku, ọmọ arábìnrin Barnaba. (Nípasẹ̀ ẹni tí ẹ̀yin ti gba àṣẹ; bí ó bá sì wá sí ọ̀dọ̀ yín, ẹ gbà á.) 11Àti Jesu, ẹni tí à ń pè ní Justu, ẹni tí ń ṣe ti àwọn onílà. Àwọn wọ̀nyí nìkan ni olùbáṣiṣẹ́ mí fún ìjọba Ọlọ́run, àwọn ẹni tí ó tí jásí ìtùnú fún mi.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.