Native Bible

Colossians 3:11 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Níbi tí kò gbé sí Giriki tàbí Júù, ìkọlà tàbí aláìkọlà, aláìgbédè, ara Skitia, ẹrú tàbí òmìnira, ṣùgbọ́n Kristi ni ohun gbogbo nínú ohun gbogbo.

Colossians 3:11 in English

Colossians 3:11 · Berean Standard Bible

Here there is no Greek or Jew, circumcised or uncircumcised, barbarian, Scythian, slave, or free, but Christ is all and is in all.

Context

9Ẹ má ṣe purọ́ fún ara yín, níwọ̀n ìgbà tí ẹ ti bọ́ ògbólógbòó ara yín pẹ̀lú ìṣe rẹ̀ sílẹ̀, 10tí ẹ sì ti gbé ìgbé ayé tuntun wọ̀, èyí tí a sọ di tuntun nínú ìmọ̀ ní ìbámu pẹ̀lú àwòrán ẹni tí ó dá a. 11Níbi tí kò gbé sí Giriki tàbí Júù, ìkọlà tàbí aláìkọlà, aláìgbédè, ara Skitia, ẹrú tàbí òmìnira, ṣùgbọ́n Kristi ni ohun gbogbo nínú ohun gbogbo. 12Nítorí náà, bí àyànfẹ́ Ọlọ́run, ẹni mímọ́ àti olùfẹ́, ẹ gbé ọkàn ìyọ́nú wọ̀, ìṣoore, ìrẹ̀lẹ̀, inú tútù àti sùúrù. 13Ẹ máa fi ara dà á fún ara yín, ẹ sì máa dáríjì ara yín bí ẹnikẹ́ni bá ní ẹ̀sùn sí ẹnìkan: bí Kristi ti dáríjì yín, gẹ́gẹ́ bẹ́ẹ̀ ni kí ẹ̀yin kí ó máa ṣe pẹ̀lú.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.