Native Bible

Colossians 2:12 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Bí a ti sin yín pọ̀ pẹ̀lú rẹ̀ nínú ìtẹ̀bọmi, tí a sì ti jí yín dìde pẹ̀lú rẹ̀ nípasẹ̀ ìgbàgbọ́ yín nínú agbára Ọlọ́run, ẹni tí ó jí dìde kúrò nínú òkú.

Colossians 2:12 in English

Colossians 2:12 · Berean Standard Bible

And having been buried with Him in baptism, you were raised with Him through your faith in the power of God, who raised Him from the dead.

Context

10ẹ̀yin sì ní ohun gbogbo ní kíkún nínú Kristi, ẹni tí i ṣe orí fún gbogbo agbára àti àṣẹ. 11Nínú ẹni tí a kò fi ìkọlà tí a fi ọwọ́ kọ kọ yín ní ilà, ni bíbọ ara ẹ̀ṣẹ̀ sílẹ̀, nínú ìkọlà Kristi. 12Bí a ti sin yín pọ̀ pẹ̀lú rẹ̀ nínú ìtẹ̀bọmi, tí a sì ti jí yín dìde pẹ̀lú rẹ̀ nípasẹ̀ ìgbàgbọ́ yín nínú agbára Ọlọ́run, ẹni tí ó jí dìde kúrò nínú òkú. 13Àti ẹ̀yin, ẹni tí ó ti kú nítorí ẹ̀ṣẹ̀ yín àti àìkọlà ará yín, mo ní, ẹ̀yin ni ó sì ti sọ di ààyè pọ̀ pẹ̀lú rẹ̀, ó sì ti dárí gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ yín jì yín; 14Ó sì ti pa ìwé májẹ̀mú nì rẹ́, tí ó lòdì sí wa, tí a kọ nínú òfin, èyí tí o lòdì sí wa: òun ni ó sì ti mú kúrò lójú ọ̀nà, ó sì kàn án mọ àgbélébùú.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.