Kolose 1:24
Colossians 1:24 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Nísinsin yìí èmi ń yọ̀ nínú ìjìyà fún un yín. Inú mi sì dùn, nítorí mo ń ṣe ìrànlọ́wọ́ láti jẹ ìyà tó ṣẹ́kù nínú ìyà Kristi fún ara rẹ̀, èyí tí ì ṣe ìjọ.
Colossians 1:24 in English
Colossians 1:24 · Berean Standard Bible
Now I rejoice in my sufferings for you, and I fill up in my flesh what is lacking in regard to Christ’s afflictions for the sake of His body, which is the church.
Context
22Ṣùgbọ́n nísinsin yìí, ó ti bá yín làjà nípa ara Kristi nípa ikú láti mú un yín lọ sí iwájú rẹ̀ ní mímọ́, aláìlábàwọ́n àti kúrò nínú ìdálẹ́bi, 23bí ẹ̀yin bá dúró nínú ìgbàgbọ́ yín, tí ẹ fi ẹsẹ̀ múlẹ̀, tí ẹ sì dúró ṣinṣin, láláìyẹsẹ̀ kúrò nínú ìrètí ti ìyìnrere ti ẹ̀yin ti gbọ́, èyí tí a ti wàásù rẹ̀ fún gbogbo ẹ̀dá lábẹ́ ọ̀run, àti èyí ti èmi Paulu ṣe ìránṣẹ́ fún. 24Nísinsin yìí èmi ń yọ̀ nínú ìjìyà fún un yín. Inú mi sì dùn, nítorí mo ń ṣe ìrànlọ́wọ́ láti jẹ ìyà tó ṣẹ́kù nínú ìyà Kristi fún ara rẹ̀, èyí tí ì ṣe ìjọ. 25Nínú èyí tí a fi ṣe ìránṣẹ́ fún gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ ìríjú Ọlọ́run tí a fi fún mi fún yín láti mú ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ṣẹ. 26Ó ti pa àṣírí ìjìnlẹ̀ yìí mọ́ fún ayérayé àti láti ìrandíran. Ṣùgbọ́n nísinsin yìí, gẹ́gẹ́ bí ìfẹ́ ọkàn rẹ̀, ó ti fihàn fún àwọn ẹni mímọ́.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.