Kolose 1:20
Colossians 1:20 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Àti nípasẹ̀ rẹ̀ láti bá ohun gbogbo làjà àwọn nǹkan tí ń bẹ láyé àti èyí tí ń bẹ ní ọ̀run, nípa mímú àlàáfíà wá nípasẹ̀ ẹ̀jẹ̀ rẹ̀, tí a ta sílẹ̀ lórí igi àgbélébùú.
Colossians 1:20 in English
Colossians 1:20 · Berean Standard Bible
and through Him to reconcile to Himself all things, whether things on earth or things in heaven, by making peace through the blood of His cross.
Context
18Òun ni orí fún ara, èyí tí í ṣe ìjọ; òun ni ìbẹ̀rẹ̀ àti àkọ́bí nínú àwọn òkú, pé nínú ohun gbogbo kí òun lè ní ipò tí ó ga jùlọ nínú ohunkóhun. 19Nítorí ìfẹ́ Ọlọ́run ni pé kí gbogbo ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ òun tìkára rẹ̀ lè máa gbé nínú rẹ̀. 20Àti nípasẹ̀ rẹ̀ láti bá ohun gbogbo làjà àwọn nǹkan tí ń bẹ láyé àti èyí tí ń bẹ ní ọ̀run, nípa mímú àlàáfíà wá nípasẹ̀ ẹ̀jẹ̀ rẹ̀, tí a ta sílẹ̀ lórí igi àgbélébùú. 21Ẹ̀yin ya ara yín nípá kúrò lọ́dọ̀ Ọlọ́run nígbà kan rí, ẹ jẹ́ ọ̀tá nínú ọkàn yín nítorí ìwà búburú yín. 22Ṣùgbọ́n nísinsin yìí, ó ti bá yín làjà nípa ara Kristi nípa ikú láti mú un yín lọ sí iwájú rẹ̀ ní mímọ́, aláìlábàwọ́n àti kúrò nínú ìdálẹ́bi,
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.