Kolose 1:17
Colossians 1:17 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ó ti wà ṣáájú kí ohunkóhun tó wà, nínú rẹ̀ ni a sì so ohun gbogbo papọ̀ ṣọ̀kan.
Colossians 1:17 in English
Colossians 1:17 · Berean Standard Bible
He is before all things, and in Him all things hold together.
Context
15Kristi ni àwòrán Ọlọ́run tí a kò le rí, àkọ́bí gbogbo ẹ̀dá. 16Nítorí nípa rẹ̀ ní a dá ohun gbogbo: àwọn ohun tí ń bẹ ní ọ̀run àti ní ayé, ohun tí a rí àti èyí tí a kò rí, wọn ìbá ṣe ìtẹ́, tàbí agbára, tàbí àṣẹ, nípasẹ̀ rẹ̀ ni a dá ohun gbogbo àti fún un. 17Ó ti wà ṣáájú kí ohunkóhun tó wà, nínú rẹ̀ ni a sì so ohun gbogbo papọ̀ ṣọ̀kan. 18Òun ni orí fún ara, èyí tí í ṣe ìjọ; òun ni ìbẹ̀rẹ̀ àti àkọ́bí nínú àwọn òkú, pé nínú ohun gbogbo kí òun lè ní ipò tí ó ga jùlọ nínú ohunkóhun. 19Nítorí ìfẹ́ Ọlọ́run ni pé kí gbogbo ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ òun tìkára rẹ̀ lè máa gbé nínú rẹ̀.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.