Native Bible

Colossians 1:10 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Àwa sì ń gbàdúrà yìí kí ẹ lè gbé irú ìgbé ayé tó yẹ fún Olúwa kí ẹ sì máa wu ú ní gbogbo ọ̀nà, kí ẹ sì máa so èso rere gbogbo, kí ẹ sì máa dàgbà nínú ìmọ̀ Ọlọ́run,

Colossians 1:10 in English

Colossians 1:10 · Berean Standard Bible

so that you may walk in a manner worthy of the Lord and may please Him in every way: bearing fruit in every good work, growing in the knowledge of God,

Context

8Ẹni ti ó sọ fún wa nípa ìfẹ́ yín nínú ẹ̀mí. 9Nítorí ìdí èyí, láti ọjọ́ tí a ti gbọ́ nípa yín, a kò sinmi láti máa gbàdúrà fún yin, tí a sì ń gbàdúrà pé kí Ọlọ́run fi ìmọ̀ ìfẹ́ rẹ̀ kún yín nípasẹ̀ ọgbọ́n àti òye gbogbo tí ń ṣe ti Ẹ̀mí. 10Àwa sì ń gbàdúrà yìí kí ẹ lè gbé irú ìgbé ayé tó yẹ fún Olúwa kí ẹ sì máa wu ú ní gbogbo ọ̀nà, kí ẹ sì máa so èso rere gbogbo, kí ẹ sì máa dàgbà nínú ìmọ̀ Ọlọ́run, 11pé kí a lè fi ipa gbogbo sọ yín di alágbára gẹ́gẹ́ bí agbára rẹ̀ àti ògo rẹ̀, kí ó lè ṣe é ṣe fún un yín láti máa tẹ̀síwájú nínú sùúrù àti ìpamọ́ra pẹ̀lú ayọ̀. 12Kí a máa dúpẹ́ nígbà gbogbo lọ́wọ́ Baba, ẹni tí ó kà yín láti jẹ́ alábápín nínú ogún àwọn ẹni mímọ́ nínú ìjọba ìmọ́lẹ̀.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.