Amosi 9:1
Amos 9:1 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Mo rí Olúwa, ó dúró ní ẹ̀bá pẹpẹ, ó sì wí pé: “Lu orí àwọn àtẹ́rígbà ìlẹ̀kùn kí àwọn òpó kí ó lè mì fọ́ wọn sí orí àwọn gbogbo ènìyàn àwọn tí ó ṣẹ́kù ni èmi yóò fi idà pa, ẹni tí ó sálọ nínú wọn kí yóò sá gbé, ẹni ti ó sá àsálà nínú wọn kí yóò gbàlà.
Amos 9:1 in English
Amos 9:1 · Berean Standard Bible
I saw the Lord standing beside the altar, and He said: “Strike the tops of the pillars so that the thresholds shake. Topple them on the heads of all the people, and I will kill the rest with the sword. None of those who flee will get away; none of the fugitives will escape.
Context
1Mo rí Olúwa, ó dúró ní ẹ̀bá pẹpẹ, ó sì wí pé:
“Lu orí àwọn àtẹ́rígbà ìlẹ̀kùn
kí àwọn òpó kí ó lè mì
fọ́ wọn sí orí àwọn gbogbo ènìyàn
àwọn tí ó ṣẹ́kù ni èmi yóò fi idà pa,
ẹni tí ó sálọ nínú wọn kí yóò sá gbé,
ẹni ti ó sá àsálà nínú wọn kí yóò gbàlà. 2Bí wọ́n tilẹ̀ wa ilẹ̀ lọ sí ipò òkú,
láti ibẹ̀ ni ọwọ́ mi yóò ti tẹ̀ wọ́n.
Bí wọ́n tilẹ̀ gun òkè ọ̀run lọ,
láti ibẹ̀ ni èmi yóò ti mú wọn sọ̀kalẹ̀. 3Bí wọ́n tilẹ̀ fi ara wọn pamọ́ ni orí òkè Karmeli,
èmi yóò wá wọn rí, Èmi yóò si mú wọn kúrò níbẹ̀.
Bí wọ́n tilẹ̀ fi ara pamọ́ fún mi sí ìsàlẹ̀ Òkun,
láti ibẹ̀ ni Èmi yóò ti pàṣẹ fún ejò kí ó bù wọ́n ṣán.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.