Amosi 4:1
Amos 4:1 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ yìí, ẹ̀yin màlúù Baṣani lórí òkè Samaria, ẹ̀yin obìnrin tí ó ń ni tálákà lára, tí ó ń tẹ aláìní mọ́lẹ̀, tí ó wí fún ọkọ rẹ̀, “Gbé wá kí a sì mu!”
Amos 4:1 in English
Amos 4:1 · Berean Standard Bible
Hear this word, you cows of Bashan on Mount Samaria, you women who oppress the poor and crush the needy, who say to your husbands, “Bring us more to drink.”
Context
1Ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ yìí, ẹ̀yin màlúù Baṣani lórí òkè Samaria,
ẹ̀yin obìnrin tí ó ń ni tálákà lára,
tí ó ń tẹ aláìní mọ́lẹ̀, tí ó wí fún ọkọ rẹ̀, “Gbé wá kí a sì mu!” 2Olúwa Olódùmarè ti fi ìwà mímọ́ rẹ̀ búra:
“Àkókò náà yóò dé nítòótọ́
nígbà tí a ó fi ìwọ̀ mú un yín lọ,
ẹni tí ó kẹ́yìn pẹ̀lú ìwọ̀ ẹja. 3Ẹni kọ̀ọ̀kan yín yóò jáde lọ
gba àárín odi yíya
a ó sì lé e yín sí Harmoni,”
ni Olúwa wí.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.