Native Bible

Acts 9:34 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Peteru sì wí fún un pé, “Aenea, Jesu Kristi mú ọ láradá; dìde kí ó sì tún àkéte rẹ ṣe.” Ó sì dìde lójúkan náà.

Acts 9:34 in English

Acts 9:34 · Berean Standard Bible

“Aeneas,” Peter said to him, “Jesus Christ heals you! Get up and put away your mat.” Immediately Aeneas got up,

Context

32Ó sì ṣe, bí Peteru ti ń kọjá lọ káàkiri láàrín wọn, ó sọ̀kalẹ̀ lọ pẹ̀lú si ọ̀dọ̀ àwọn ènìyàn mímọ́ ti ń gbé ni Lida. 33Níbẹ̀ ni ó rí ọkùnrin kan ti a pè ní Aenea tí ó ti dùbúlẹ̀ lórí àkéte ni ọdún mẹ́jọ, ó ní ààrùn ẹ̀gbà. 34Peteru sì wí fún un pé, “Aenea, Jesu Kristi mú ọ láradá; dìde kí ó sì tún àkéte rẹ ṣe.” Ó sì dìde lójúkan náà. 35Gbogbo àwọn tí ń gbé Lida àti Ṣaroni sì rí i, wọn sì yípadà sí Olúwa. 36Ọmọ-ẹ̀yìn kan sí wà ní Joppa ti a ń pè ni Tabita (èyí tí ó túmọ̀ sí Dọkasi); obìnrin yìí pọ̀ ni iṣẹ́ oore, àti ìtọrẹ àánú ṣíṣe.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.