Ìṣe àwọn Aposteli 9:29
Acts 9:29 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ó ń sọ̀rọ̀ lòdì sí àwọn ará Helleni, ó sì ń jà wọ́n ní iyàn; ṣùgbọ́n wọn ń pète láti pa a.
Acts 9:29 in English
Acts 9:29 · Berean Standard Bible
He talked and debated with the Grecian Jews,* but they tried to kill him.
Context
27Ṣùgbọ́n Barnaba mú un, ó sì sìn ín lọ sọ́dọ̀ àwọn aposteli, ó sì sọ fún wọn bí ó ti rí Olúwa ní ọ̀nà, àti bí ó ti fi ìgboyà wàásù ní Damasku ní orúkọ Jesu. 28Saulu sì wà pẹ̀lú wọn, ó ń wọlé, ó sì ń jáde ní Jerusalẹmu. Ó sì ń fi ìgboyà wàásù ni orúkọ Olúwa. 29Ó ń sọ̀rọ̀ lòdì sí àwọn ará Helleni, ó sì ń jà wọ́n ní iyàn; ṣùgbọ́n wọn ń pète láti pa a. 30Nígbà tí àwọn arákùnrin sì mọ̀, wọ́n mú sọ̀kalẹ̀ lọ sí Kesarea, wọ́n sì rán an lọ sí Tarsu. 31Nígbà náà ni ìjọ wà ni àlàáfíà yíká gbogbo Judea àti ni Galili àti ni Samaria, wọn ń fẹsẹ̀múlẹ̀, wọn ń rìn ní ìbẹ̀rù Olúwa, àti ni ìtùnú Ẹ̀mí Mímọ́, wọn ń pọ̀ sí i.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.