Ìṣe àwọn Aposteli 8:24
Acts 8:24 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Nígbà náà ni Simoni dáhùn, ó sì wí pé, “Ẹ gbàdúrà sọ́dọ̀ Olúwa fún mi, kí ọ̀kan nínú ohun tí ẹ̀yin tí sọ má ṣe bá mi.”
Acts 8:24 in English
Acts 8:24 · Berean Standard Bible
Then Simon answered, “Pray to the Lord for me, so that nothing you have said may happen to me.”
Context
22Nítorí náà ronúpìwàdà ìwà búburú rẹ yìí, kí ó sì gbàdúrà sọ́dọ̀ Ọlọ́run bóyá yóò dárí ète ọkàn rẹ jì ọ́. 23Nítorí tí mo wòye pé, ìwọ wa nínú òróǹró ìkorò, àti ní ìdè ẹ̀ṣẹ̀.” 24Nígbà náà ni Simoni dáhùn, ó sì wí pé, “Ẹ gbàdúrà sọ́dọ̀ Olúwa fún mi, kí ọ̀kan nínú ohun tí ẹ̀yin tí sọ má ṣe bá mi.” 25Nígbà tí wọn sì ti jẹ́rìí, tiwọn ti sọ ọ̀rọ̀ Olúwa, Peteru àti Johanu padà lọ sí Jerusalẹmu, wọ́n sì wàásù ìyìnrere ni ìletò púpọ̀ ti àwọn ará Samaria. 26Angẹli Olúwa sì sọ fún Filipi pé, “Dìde kí ó sì máa lọ sí ìhà gúúsù, sí ọ̀nà ijù, tí ó ti Jerusalẹmu lọ sí Gasa.”
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.