Ìṣe àwọn Aposteli 7:37
Acts 7:37 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
“Èyí ni Mose náà ti ó wí fún àwọn ọmọ Israẹli pé, ‘Ọlọ́run yóò gbé wòlíì kan bí èmi dìde nínú àwọn ènìyàn yín.’
Acts 7:37 in English
Acts 7:37 · Berean Standard Bible
This is the same Moses who told the Israelites, ‘God will raise up for you a prophet like me from among your brothers.’*
Context
35“Mose náà yìí tí wọ́n kọ̀, wí pé, ‘Ta ni ó fi jẹ olórí àti onídàájọ́?’ Òun náà ni Ọlọ́run rán lọ láti ọwọ́ angẹli, tí ó farahàn án ní pápá, láti ṣe olórí àti olùdáǹdè. 36Òun ni ó mú wọn jáde, lẹ́yìn ìgbà tí ó ṣe iṣẹ́ ìyanu àti iṣẹ́ àmì ní ilẹ̀ Ejibiti, àti ni Òkun pupa, àti ni aginjù ní ogójì ọdún. 37“Èyí ni Mose náà ti ó wí fún àwọn ọmọ Israẹli pé, ‘Ọlọ́run yóò gbé wòlíì kan bí èmi dìde nínú àwọn ènìyàn yín.’ 38Èyí náà ni ẹni tí ó wà nínú ìjọ ní ijù pẹ̀lú angẹli náà tí ó bá a sọ̀rọ̀ ní orí òkè Sinai, àti pẹ̀lú àwọn baba wa; ẹni ti ó gba ọ̀rọ̀ ìyè láti fi fún wa. 39“Ṣùgbọ́n àwọn baba wa kò fẹ́ gbọ́ tirẹ̀. Dípò bẹ́ẹ̀, wọ́n kọ̀ ọ́ sílẹ̀, àti pé nínú ọkàn wọn, wọn fẹ́ yípadà lọ sí ilẹ̀ Ejibiti.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.