Ìṣe àwọn Aposteli 7:33
Acts 7:33 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
“Olúwa sì wí fún un pé, ‘Bọ́ bàtà rẹ kúrò ní ẹsẹ̀ rẹ, nítorí ibi tí ìwọ dúró sí i nì ilẹ̀ mímọ́ ni.
Acts 7:33 in English
Acts 7:33 · Berean Standard Bible
Then the Lord said to him, ‘Take off your sandals, for the place where you are standing is holy ground.
Context
31Nígbà tí Mose sì rí i, ẹnu yà á sí ìran náà; nígbà tí ó sì súnmọ́ ọn láti wò ó fín, ohùn Olúwa kọ sí i, 32wí pé ‘Èmi ni Ọlọ́run àwọn baba rẹ, Ọlọ́run Abrahamu, Ọlọ́run Isaaki, àti Ọlọ́run Jakọbu,’ Mose sì wárìrì pẹ̀lú ìbẹ̀rù, kò sì dáṣà láti wò ó mọ́. 33“Olúwa sì wí fún un pé, ‘Bọ́ bàtà rẹ kúrò ní ẹsẹ̀ rẹ, nítorí ibi tí ìwọ dúró sí i nì ilẹ̀ mímọ́ ni. 34Ní rí rí, mo ti rí ìpọ́njú àwọn ènìyàn mi tí ń bẹ ni Ejibiti, mo sì ti gbọ́ ìkérora wọn, mo sì sọ̀kalẹ̀ wá láti gbà wọ́n. Wá nísinsin yìí, Èmi ó sì rán ọ lọ sí ilẹ̀ Ejibiti.’ 35“Mose náà yìí tí wọ́n kọ̀, wí pé, ‘Ta ni ó fi jẹ olórí àti onídàájọ́?’ Òun náà ni Ọlọ́run rán lọ láti ọwọ́ angẹli, tí ó farahàn án ní pápá, láti ṣe olórí àti olùdáǹdè.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.