Ìṣe àwọn Aposteli 7:24
Acts 7:24 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Nígbà tí ó sì rí ọ̀kan nínú wọ́n tí ará Ejibiti kan ń jẹ́ ní ìyà, ó gbèjà rẹ̀, ó gbẹ̀san ẹni tí wọ́n jẹ ní ìyà nípa lílu ará Ejibiti náà pa.
Acts 7:24 in English
Acts 7:24 · Berean Standard Bible
And when he saw one of them being mistreated, Moses went to his defense and avenged him by striking down the Egyptian who was oppressing him.
Context
22A sì kọ́ Mose ni gbogbo ọgbọ́n ara Ejibiti, ó sì pọ̀ ni ọ̀rọ̀ àti ní ìṣe. 23“Nígbà tí Mose di ọmọ ogójì ọdún, ó sọ sí i lọ́kàn láti lọ bẹ àwọn ọmọ Israẹli ará rẹ̀ wò. 24Nígbà tí ó sì rí ọ̀kan nínú wọ́n tí ará Ejibiti kan ń jẹ́ ní ìyà, ó gbèjà rẹ̀, ó gbẹ̀san ẹni tí wọ́n jẹ ní ìyà nípa lílu ará Ejibiti náà pa. 25Mose rò bí àwọn ará òun mọ̀ pé Ọlọ́run yóò ti ọwọ́ òun gbà wọn; ṣùgbọ́n wọn kò mọ̀. 26Ní ọjọ́ kejì Mose yọ sí àwọn ọmọ Israẹli méjì bí wọ́n ti ń jà. Òun si fẹ́ parí ìjà fún wọn. Ó wí pé, ‘Ènìyàn mi, ará ni ẹ̀yin; èéṣe tí ẹ̀yin fi ń ṣe ohun tí kò tọ́ sí ara yín?’
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.