Native Bible

Acts 7:19 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Òun náà ni ó ṣe àrékérekè sí àwọn ìbátan wa. Wọn sì hùwà búburú sí àwọn baba wa, tó bẹ́ẹ̀ tí wọ́n fi já àwọn ọmọ ọwọ́ wọn kúrò lọ́wọ́ wọn nítorí kí wọn má ṣe yè.

Acts 7:19 in English

Acts 7:19 · Berean Standard Bible

He exploited our people and oppressed our fathers, forcing them to abandon their infants so they would die.

Context

17“Nígbà tí àkókò tí Ọlọ́run yóò mú ìlérí tí ó ṣe fún Abrahamu ṣẹ kù sí dẹ̀dẹ̀, àwọn ènìyàn wa ń gbèrú si gidigidi ní iye ní ilẹ̀ Ejibiti. 18Ṣùgbọ́n ọba tuntun mìíràn tí kò mọ Josẹfu jẹ ní ilẹ̀ Ejibiti. 19Òun náà ni ó ṣe àrékérekè sí àwọn ìbátan wa. Wọn sì hùwà búburú sí àwọn baba wa, tó bẹ́ẹ̀ tí wọ́n fi já àwọn ọmọ ọwọ́ wọn kúrò lọ́wọ́ wọn nítorí kí wọn má ṣe yè. 20“Ní àkókò náà ni a bí Mose ọmọ tí ó se iyebíye, tí wọn sí bọ́ lóṣù mẹ́ta ni ilé baba rẹ̀. 21Nígbà tí wọn sí gbe é sọnù, ọmọbìnrin Farao gbé e, ó sì tọ ọ́ dàgbà gẹ́gẹ́ bí ọmọ ara rẹ̀.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.